ÌFÉ
Ìfé, hmmmm! Òrò nlá.....
ÌFÉ jé oun kan tí o n má fún mi ní ìwúrí nígbogbo ìgbà. Kòsí nnkan ti ó dàbí kí Ènìyàn ní eniti rè. Orí mi a sì ma dìde jan nígbàtí mo bá rí Olólùfé méjì tí wón nife ara won dénú; ìfé òtító, tí kìí n se ìfé ètàn. Ara mi áyá Gaga. ÌFÉ kojá oun àfenuso. Kòsí nnkan tí ó da tó ki Ènìyàn ní enìkejí, alábàárò, eegun ìhà eni. Ilé ayé yi, ìfé ni ìpìnlè re.
Gégébí òrò Yoruba, ìbí tí ìfé bá ti wa, wón ti ní gbogbo nnkan. Ìfé ni àkójá òfin - Òrò ìfé kojá oun ànfii owó ehnhe mu! Ìfé tí a ma mú ni se oun tó o lérò pé o lè e. A ma so eni di Èyan tútù. A ma yíni níwà padà. Ìfé ò kan ojó orí, kó kan ipó, olá, gbajúmò, àbí ewà. Ti ìfé bá dé, ó dé nu. Ìfé a ma dùn, a sì ma korò bí ewúro nígbàmi. Éyin ará mi, òrò ìfé kojá ahhhh! Ìfé a má so ojo di akin. Agbára ìfé pò!
Ní òpòlopò ìgbà tí iná ìfé bá bèrè sí n jó, a dà bíi pe kó má kù. Nígbàmi, a o kín fe, kí òpin déba. Sùgbón àdìtú ni òrò yii. Ò kojá òyè gbogbo èdá. Ti òpin bá dé bá ìfè, ewúro ibè nùú - nínú àyè báyìí, òpin tó dé bá le má jé èbi enìkankan, amo òrò Olórun gbódò se. Yálà, àwon àpèere kòòkan fara hàn, abi àjòsepò òun tí n ni è. A ma fún ra eni láàyè - láti lè má ba nnkan jé. Irú ìgbésè yìī, a ma le láti gbé pàápàá jùlo ní àkókò tí iná ìfé oun n jó ni àjóyà, àbí ìfé òun pò.
Èémì a tún ma selè nígbàtí ìjákule bá selè láti apá kan si ìkejì. A má mu okan eni le láti ma fun ìfé ní àyè mò. Ààmó, ilé ayé ò rí bee - "tí esin bá da ni, a ma tun gún ni". Ìfé tí o rí ìjákulè níbè, o ní ìdí. Tàbí nígbàmi ki òòkan ma wùwà tí o bójú mo; sìná sise, ìwà àìbìkítà. Ewúro ìfé ní àwon nnkan wònyen. Sùgbón aàdùn rè a ma pòjù ìkorò re lo.
Tí mo bá rí àwon Olólùfé àgbà méjì, inú mi a ma dùn. Kíni ìdí? Òpòlopò nnkan ló rò mo ìfè; sùúrù, àforíjì, ìfaradà, àmójúkúrò, ìwà pèlé, àti béè béè lo. Nnkan wònyi ló má n jé ìwúrì fún mi. Sí ìwo, ìwàpò èyàn méjì gégébí okoláya fún bi Àádóta Odún, sé eré ni? Kí n sé eré béèni ki n se àwàdà. Isé takuntakun ni. Òpòlopò nnkan ló rò mo.
Adùn ìfé o ló n ka. Ó pò jaburata!
- Ìfé a má mu ìfòkànbalè ba oo, pèlú ìgbàgbó pé o ní tìre.
- Ìfé òtító a ma fun o ní okun àti agbára.
- Àdágbé àdáfà á kúrò ninu òrò èdá.
- Ìgboyà á dé bá o.
- Ara gbígbòn yóò dìkún, àti béè béè lo. Ànfààní re po, amoo, e jé ká da dúró níbí.
Ní ìtèsìwájú, kíni ó se pàtàkì ju ìfé lo, e jé á yèwón wò;
Tí o n bá gbìyànjú láti ni àjosepò ti yoo pé pèlú enití o nífè, àwon nnkan wònyí gbódò bó si ìwáyè láàrín egbé méjèjì:
• Ifokàntan
• Àánú.
• Ìdúró ti ara eni nígbogbo ìgbà.
• Òtító síso: Àìmoye okò ìfé ló ti fi iwájú sanpon láti ara iro!
Mo lérò pé oro mi yé.
Ní àkótán, àti ìparí; ÌFÉ òtító sì wa, o kàn sòwón ni. Olórun á si se ni ìròrùn fún enìkòòkan wa. Mo sì tún bo gbàá ni àdúrà pé Olórun á fún gbogbo wa ni ìfè tí á bá wa kalé. Àwon tí won ti rí, Olórun ò ní pa iná ìfé yín. A ò ní pa lára níbi ìfé.
Eseun lópòlopò. Mo dúpé.
Arákùnrin àti arábìnrin, fún ìfé làyè nínú ayé re! Ìfé se pàtàkì.
Ònímò-èró Opéyemí BELLO.
Ònkòwé òde òní.
07087295641.